1. Omi kì í kún bo’ni dégà ọrùn, ká tún máa wá ‘gbá ta ó fi mu ún.
  2. Omi tí’gbá gbọ́n tó tẹ̀ wọrọkọ, t’ábọ́ bá gbọ́n ọn, yóò gbó túútú.
  3. Omi gbígbóná tó dàpọ̀ mọ́ tútù, Ọlọ́run ló ń yanjú ẹ̀.
  4. Omi la fi ń pẹ̀rọ̀ ilẹ̀.
  5. Omi táa ó mu kò ní ṣàn kọjá ẹnu ẹni.
  6. Omi ò ṣe é ta ní kókó.
  7. Omi táa fi se ẹyin kì í mọ́ ẹyin lára.
  8. Omi tó mọ níwọ̀n là á dá’lá sí.
  9. Omi adágún t’òun àbàtà l’alákàn lè wẹ̀

10.Omi lẹ̀rọ̀ àlejò

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here