ỌLỌ́RUN NI (Yoruba Poetry)

0
93
Yoruba Poetry

Fùlengefùlenge àkàrà;
Kò kúkú sé lẹ́yìn erèé láyé.
Gàlègàlè ẹja l’álẹ̀-odò,
Kò kúkú sé lẹ́yìn omi.
Igba ọgbà,
Tó dúró gbágbáágbá;
Ó dá mi lójú gbamgba,
Igi ló wà lẹ́yìn ọgbà,
L’ọgbà fi gún rekete.
Aṣẹ̀dá l’Alátìlẹyìn àwa ẹ̀dá.
Bí ‘ò sí t’Olúwa ni;
Ọ̀lẹ l’ọmọ ẹ̀dá ènìyàn.
Gbogbo ohun tó wù ‘á rí dá,
Gbogbo ohun tó wù ‘á rí dà.
Kò kúkú sé lẹ́yìn Olúwa Ọba.
Ọba-òkè nigi lẹ́yìn ọgbà ẹ̀dá.
Kì í ṣọgbọ́n;
Bẹ́ẹ̀ ni ‘ì í ṣagbára.
Ète ‘ò ràn án.
Àlùmọ̀kọ́rọ́í ‘ò gbé e.
Àní sẹ́,
Ọlọ́run ni, kì í ṣèèyàn.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here