Onírúurú ìpènijà;
Ọ̀kan-‘ò-jọ̀kan ìdààmú,
Oníranǹran aápọn ló forímù;
Farasin s’ójú-ọ̀nà aṣeyege.
Ìtàkùn ìjákulẹ̀ ń bẹ níbẹ̀;
T’òun t’àbàtà èérí.
Ká tó k’ógo já l’ókè-erùpẹ̀,
Dandan ni ká f’ara yẹ́gbin.
Háà!!!
Ojú ti rí tó;
Ojú ti rí tò;
Ojú ti rí to too to!
K’ọ́mọ ẹ̀dá ó tó gb’ẹ́rù dórí.
Akọ iṣẹ́ ni wọ́n-ọ́n ṣe.
Ojú-ọ̀nà àṣeyọrí kìkì ìdààmú;
Ságbàsúlà ojúmọmọ,
Àìsùn lọ́gànjọ́.
B’ó bá tún di ní kùtùkùtù;
A tún di jáláńkáto jáláńkáto.
Ojú-ọ̀nà àṣeyọrí kìkìdá ìjàngbọ̀n.
Òrìșà jẹ́ n dàbí onílé yìí l’ọ̀pọ̀ ń wí.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ni ò tiẹ̀ mọ̀,
Pé kílé ó tó dúró ringindin,
Kì í șè’mọ̀ràn òòjọ́.
Onírúurú èébú;
Ọ̀kẹ́-àìmọye ìyọșùùtì,
Ẹdugbẹ ìwọ̀sí ńlá ńlá,
Lójú-ọ̀nà aṣeyege.
Ìforítì, ìfojúsùn òun ìfaradà,
La fi í ṣ’àṣemólú ṣàṣeyege.
Ojú-ọ̀nà ‘ò kúkú mù láyé,
Ọ̀nà tá a bá ń tọ̀,
Bó bá ti j’ọ́nà ẹ̀tọ́.
‘Un l’ọmọ ẹ̀dá ti í ṣaseyege.
Ẹni a ń bá tayò là á wò,
A kì í wo ti fèyíjẹẹ́ rárá.
Ẹ jẹ́ á kọ́gbọ́n lára òkú Ìmàle;
Ibii wọ́n ń lọ làwọ́n-ọ́n gbájúmọ́.
Ká tó dé’bùdó àṣeyege,
Ìfojúsùn tó lọ́ọ̀rìn dòòdò ló tọ́.
Àdúrà tó gbóná janjan-anjan,
Ni ẹ jẹ́ ká tún wò ní bàbàrà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here