ỌJỌ́-ÌBÍ Ẹ̀DÁ

0
110
Yoruba Birthday Poetry

Ọjọ́ ńlá l’ọ̀jọ́ a bíni sáyé.

Ọjọ́ tá a ké wẹ́ẹ̀ wẹ́ẹ̀,

Ọjọ́ kan kùù tó yakin ni.

Ọjọ́ a kọ́kọ́ mumi ayé pàá,

Ọjọ́ kan gbòógì,

Tí í ránni gẹ́gẹ́ bí ojú ooju ni.

Ọjọ́ ìdùnnú l’ọjọ́ ọ̀hún jẹ́,

Ọjọ́ tí t’ẹbí t’ará ń fò fáyọ̀.

Mo níran ọjọ́ mo d’áyé lónìí.

Mo yí gbirigidi nílẹ̀pẹ̀pẹ̀,

Mo f’ògo fÓníbú-ọrẹ.

Ọ̀pọ̀ la jọ d’áyé l’ọ́jọ́ ọ̀hún,

Tí wọ́n ti ṣán lọ bí ẹyẹ.

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ló ń bẹ bí aláìsí.

Omilẹngbẹ ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ràrìnnù.

Kí ni n ó jẹ gbàgbé ọjọ́-ìbí mi?

Ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n,

Oșù karùn-ún ọdọọdún ni.

Ọjọ́ náà rèé bí àná,

Tí Ìgè Àdùbí pariwo mo wọ̀rú ẹ̀.

Mo wọ̀rú ẹ̀, mo wọ̀rú ẹ̀;

Șá l’ẹkún ọmọ tuntun.

Abéjidé,

Ọjọ́ ńlá l’ọjọ́ mo b’éji dé sáyé.

T’ọ̀rẹ́  t’ọ̀tá ló ń ṣe mí ní máa wolẹ̀ mọ́ràba.

Adéṣínà dé, ó șínà f’áwọn òbí ẹ̀.

Ilé-ọlá la bímọ ọ̀hún sí,

Ló șe ń jẹ́ Ọmọ-ọba.

Baba tó lọ lọ́jọ́sí dẹ̀yìnbọ̀,

Ayé tún ní Babátúndé ni í ṣe.

Babátúndé Adéṣínà ọ̀hún náà rèé,

Òròmọdìẹ ọjọ́sí ṣe bẹ́ẹ̀ ó dàkukọ.

Màjèṣín ọjọ́ un àná,

Ṣe bí eré,

Ó wáá d’ọ̀dọ́langba.

Mo ṣogún,

Mo șọgbọ̀n,

Àláùrà, jẹ́ n le nígba-nígba.

Kí n pẹ́ láyé,

Kí n má pẹ́ ìpẹ́-ìyà.

Owó ńlá ńlá ni kó máa bá mi gbé.

Ọmọ alábáríkà,

Ni O ṣ’àwọn ọmọ tó o bá fún mi Olúwa.

Àtubọ̀tán ẹ̀dá ló jà jù,

K’átubọ̀tán mi ó má bàjẹ́.

Kó rí bẹ́ẹ̀,

Kó șẹ bẹ́ẹ̀ fún gbogbo afẹ́nifẹ́re.

Ń’torí gbogbo ohun Èwí Ayé bá wí,

Ni Ẹ̀gbà Ọ̀̀run ń gbà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here