Ariwó ta n’ígbó,
Ẹnìkan ‘ò gbọ́ n’ílé.
Aginjù mì tìtì,
A ò gbọ́ lẹ́lùjù-ọ̀dàn.
Kowéè ń ké,
Gbogbo ẹyẹ oko pa lọ́lọ́,
Akọni lọ.
Ṣebí erin ló wó nígbó tí kò lè dìde,
Àjànàkú ló nalẹ̀ láìrò tẹ́lẹ̀.
Àgbà Ọ̀jọ̀gbọ́n, ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà,
Nímọ̀ èdè àti àṣà Yorùbá,
Nikú mú lọ lójijì.
Akínwùmí ọmọ Ìṣọ̀lá,
Làlùmúńtù ṣe bẹ́ẹ̀ yọwọ́ rẹ̀,
Nínú àwo tánganran.
Oròjídé ni àsàráyílù yẹsẹ̀ rẹ̀ láwùjọ olùkọ́ Yorùbá
Ní kùtù òwúrọ̀, ọjọ́ Àbámẹ́ta,
Ọjọ́ kẹtàdínlógún, ọdún 2018.
Nikú wọlé láìkànkùn,
Tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ ṣílẹ̀kùn ‘bodè ọ̀run f’ẹ́ni wa.
Ká tó r’érin ó dígbó,
Ká tó r’ẹ́fọ̀n ó dọ̀dàn,
Ká tó rẹ́ni bí Akínwùmí,
Ó tún dayé àtúnwá,
Ó dojú àlá,
Ó di bẹ́ni ń jọni,
Béèyàn ń jọ̀́nìyàn.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Faransé
Ni baba kọ́ ní Fásitì Ìbàdàn,
Síbẹ̀, ìlọsíwájú èdè Yorùbá ni wọ́n fọn rere rẹ̀,
Ni wọ́n yàn láàyò dọjọ́ ogbó.
Akínwùmí ló ní kí wọ́n yàǹda òun,
P’óun lè fèdè Yorùbá ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tàwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n máa ń ṣe (Inaugural lecture).
A won ìgbìmọ̀ fárígá,
Wọ́n láwọn kò gbà pé àfi kó lo èdè Gẹ̀ẹ́sì bí tàwọn yòókù.
Òun náà sì ní kí wọ́n fọwọ́ mú ìdánilẹ́kọ́ọ́ wọn.
Ẹ ò rí i pé baba yìí tó kí,
Ó tó kì,
Ó tó ẹni àá gbóṣùbà bàǹbà fún.
Baba yìí wà lára àwọn akọni,
Tó jà kí èdè Yorùbá má lè rẹ̀yìn láwùjọ èdè.
Oròjídé wà lára àwọn tí kò jẹ́ kédè Yorùbá parẹ́.
Bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀,
Wọn a máa mú èdè Yorùbá wu ni.
Ọ̀pọ̀ àwa tí kò mọ̀ yín lójúkojú,
La kọ́ ẹ̀kọ́ lára àwọn ìwé tí ẹ ti kọ.
Ṣebí bónírèsé kò fíngbá mọ́,
Èyí tó ti fín sílẹ̀ kò lè parun.
Oròjídé ọmọ Ìṣọ̀lá,
Gbogbo Fásitì ìlú Ìbàdàn ń ṣelédè lẹ́yìn rẹ.
Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ló ń ṣelédè lẹ́yìn rẹ.
Gbogbo ọmọ Oòduà pátá ló ń ṣelédè lẹ́yìn rẹ.
Bóo ti ṣayé ire,
Bóo dọ́run o ṣọ̀run ‘re.

Short Biography of Professor Akínwùmí Ìṣọ̀lá

Professor Akínwùmí Ìṣọ̀lá is a Nigerian Playwright, scholar, and a cultural activist that the Nigeria community lost to the cold hand of death on February 17, 2018. He earned his Bachelor degree in French from the University of Ibadan later a Masters Degree in Yorùbá Literature from the University of Lagos, and he obtained his Doctorate degree from Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University. The first play he wrote was Ẹfúnṣetán, he later wrote Ó le kú. It is important to note that he was the only Yorùbá professor who never delivered inaugural lecture because he insisted to deliver his speech in Yorùbá Language.

5 COMMENTS

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here