June 12 Democracy Day

Ọjọ́ náà rèé bí àná.
Ọjọ́ tí ‘ò yé máa ránni bí ooju.
Ọjọ́ kan gbòógì;
T’ọ́mọ Nàìjá f’ohùn șọ̀kan.
Ọjọ́ tá a dìbò bó ti tọ́.
Ọjọ́ kan kùù;
Tá a dìbò gẹ́gẹ́ bó ti yẹ.
Láìwo tẹ̀sìn,
Láìfi tẹ̀yà ṣe.
Ọmọ Nàìjíríà ṣeraa lóșùșù-ọwọ̀.
A dìbò ọ̀hún tán,
A ș’ojúṣee wa bó ti yẹ.
A wá ń retí k’ọ́n fèsì ìbò.
A retí remú,
Etí kọ̀, kò ṣeé re rekende.
A p’ọ̀rọ̀ ọ̀hún lówè,
Ó láró nínú.
Àf’ìgbà a tún gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì bọ́lugi.
Annulment l’òyìnbó àràmàǹdà.
Ràbàràbà ọ̀rọ̀ yìí,
Ní MKO ọmọ Abíọ́lá bá lọ.
Ẹgbẹlẹmùkú ẹ̀mí ló ṣe bẹ́ẹ̀,
Ló tún ṣòfò dànù.
Gídá gìdà gídá, igi dá.
Bàbáńgídá pa kádàrá dà.
Màràdónà gé wa títí,
Ọkọ Mèrí ṣe wá ṣìbáṣìbo.
Baba Eléjìí-ọ̀ràn ní Miná,
Ó b’ayé jẹ́ kì í ṣàwàdà.
Kò pẹ́ jọjọ,
Bẹ́ẹ̀ ni ‘ò jìnnà títí.
Onígòdúdú tẹ́wọ́ gbàjọba.
Lẹ́yìn Șónẹ́kàn ni mò ń wí.
Kúkúrú bí Ikú jayé bí ẹní jẹșu.
Nàìjíríà ‘ò le gbàgbé ẹ̀ láyé.
Șé t’owó tó jí ni ká wí ni!
Àb’áwọn ẹ̀mí tó ṣòfò dànù!
Hùn-ùn,
N ‘ò tún mọ’hun ọmọ Nàìjá ń fẹ́,
Bí kì í bá ń ṣeṣẹ́ẹre.
Bùhárí sebẹ̀ àtẹ́rọ̀gọ̀jì tán,
Alákọrúwo ẹ̀dá ní ‘ò ṣeun.
Ọkọ Aisha buwọ́lu June 12,
Àwọn ọlọ̀tẹ̀ tún ń pàátó.
Èèyàn kọ́ l’Ọbásanjọ́,
Tó f’odidi ọdún mẹ́jọ gbáko jẹ,
Ọmọ Oòduà lỌbásanjọ́,
Ọmọ bíbí ìlú Ẹ̀gbá ní í ṣe.
Kódà,
Ọmọọ kíláàsì l’Abíọ́lá òun Àrẹ̀mú.
Síbẹ̀,
Ọkọ Stella ‘ò rí ǹkan ṣe sí i.
Ọmọ Fúlàní wá ṣ’ohun tó tọ́ tán,
Ọmọ Yorùbá tún ń dìtẹ̀.
Hábà, kí ló dé ọmọ Yorùbá!
Àfọ̀tẹ̀,
Àfi rìkíṣí.
Àfi rìgímọ̀,
Àfàbòsí.
Ohun Bùhárí bá fi ṣẹ̀ yín,
Ẹ wá ṣàlàyé ní wáálíà.
June 12.
Ègbé ni f’áwọn tó fi ọ́ ṣèrú.
June 12.
Ìbùkún ni f’ẹ́nì ó fi ọ́ șòótọ́.
June 12.
Mo lu Bùhárí lọ́gọ-ẹnu.
Iṣẹ́ tó yakin ni baba Zaara ṣe.
T’ẹlẹ́gàn ló jù.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here