Yéké, l’ó yé Olúwa Ọba.

Ìrìnkèrindò ọmọ ènìyàn;

Kedere l’ó hàn sÉdùmàrè.

K’á sáré sáré;

Nítorí ọsàn.

K’á pọ̀șẹ̀șẹ̀ pọ̀șẹ̀șẹ̀;

Nítorí àtimusàn.

Șáká l’ó dájú;

Ọba-òkè ní í fúnni l’ọ́sàn t’ó dùn mu.

Ìlàkàkà ‘ò ràn án;

Ohun gbogbo,

Gbogbo ohun ń bẹ lọ́wọ́ àkúnlẹ̀yàn.

Èrò inú ọkọ̀ yìí ooo,

Ẹ jẹ́ ká ṣe pẹ̀lẹ́.

K’á rìnrìn-àjò ayé b’ó ti yẹ.

K’á má gb’ọ̀nà àìtọ́.

K’á le gúnlẹ̀ ayọ̀ nígbẹ̀yìn.

Àjò láyé.

Arìnrìn-àjò lèèyàn.

Ọ̀run nilé;

Èdùà l’ó l’àbọ̀ọ wa gbogbo.

Ọba-òkè jẹ́ k’á le jábọ̀ tó dùn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here