Orúkọ Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀ Yorùbá

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé ọjọ́ méje ló wà nínú ọ̀sẹ̀ kan, àwọn Gẹ̀ẹ́sì sì ní orúkọ tí wọ́n sọ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ìwádìí tí a ṣe fihàn pé láti ara àwọn òrìṣà ni àwọn òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì ti sọ orúkọ ọjọ́ ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Bákan náà ni ọmọ ṣe ṣorí nínú èdè Yorùbá. A ó máa ṣe àfihàn òrìṣà tí ẹ̀yà Yorùbá àti àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń bọ tí wọ́n fi sọ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lórúkọ.

Ọjọ́ Àìkú: Ọjọ́ yìí ni ọjọ́ kìíní nínú ọ̀sẹ̀. Òrìṣàálá tí í ṣe Ọbàtálá ni àwọn ẹ̀yà Yorùbá ń bọ lọ́jọ́ náà.
Ọjọ́ Ajé: Èyí ni ọjọ́ kejì ọ̀sẹ̀. Òrìṣà-Oko ni wọ́n ń bọ lọ́jọ́ yìí.
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun: Èyí ni ọjọ́ kẹta ọ̀sẹ̀. Ògún ni òrìṣà tí wọ́n ń bọ lọ́jọ́ náà.
Ọjọ́ Rùú: Ọjọ́ Rùú tí í ṣe ọjọ́ kẹrin. Ifá ni wọ́n ń rú ẹbọ sí lọ́jọ́ yìí.
Ọjọ́ Bọ: Èyí ni ọjọ́ karùn-ún ọ̀sẹ̀. Ọjọ́ yìí ni wọ́n máa ń bọ Ṣàngó.
Ọjọ́ Ẹtì: Ọjọ́ Ẹtì ni ọjọ́ kẹfà nínú ọ̀sẹ̀. Ọjọ́ yìí ni wọ́n máa ń bọ Yemọja.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta: Èyí ni ọjọ́ keje nínú ọ̀sẹ̀. Ọjọ́ yìí ni wọ́n máa ń bọ Èṣù Láàlú.

DEITIES ASSOCIATED WITH DAYS OF THE WEEK

SUNDAY: The first day of the week. It’s named after the Sun.
MONDAY: The second day of the week. The name was derived from the Moon.
TUESDAY: The third day of the week. It’s named after a deity called Tiu, which is the deity of War.
WEDNESDAY: The fourth day of the week. It’s named after a deity called Wodin.
THURSDAY: The fifth day of the week. It was named after a deity called Thor, which means thunder.
FRIDAY: The sixth day of the week. It was named after a goddess called Freyer. She is the deity of beauty and love.
SATURDAY: The seventh day of the week. It was named after Saturn.

5 COMMENTS

  1. Hmmmm! Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá á yé mi báyìí pé kò sí bí ọ̀bọ ṣe sorí tí ìnàkí ò ṣe ni ọ̀rọ̀ orúkọ ọjọ́ lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì. Kudos to you Àbáláyé Nigeria.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here