B’ágbọ́n bá fẹ́ șoro;
A k’ìdí bọlé.
B’áláàmù ó bàá șoro;
A k’ìdí bàlàpà.
Bí Șàngó Olúkòso ó bàá șoro;
A máa kọ mọ̀nà l’ójú ọ̀run.
Abéjidé Ìgè Àdùbí.
Mo șetán, tí n ó wìí winrínwinrìn lédè.
Àní ṣé,
Alénibáre l’ọmọ ẹ̀dá láyé.
Afàìmọ̀-lé’ni-dé’pò-ọlà l’ọmọ ẹ̀dá èèyàn.
Ó yá,
Ẹ jẹ́ á níran ìwà-ǹ-wáyé.
Ká rántí ìgbàanì.
Àwọn ẹ̀gbọ́n ló sòpàǹpá lọ́jọ́sí;
T’ọ́n gbìmọ̀pọ̀ ju Yésúfù sí kànga.
Wọ́n bínúu kádàrá títí;
Wọ́n f’àìmọ̀ lé Jósẹ́fù alálàá báre ni.
Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀;
Yésúfùú padà wá dádé.
Ojú wá ti gbogbo abínúẹni.
Ibii wọ́n ní gbégbé ó má gbèé ló gbé.
Ibii wọ́n ní tẹ̀tẹ̀ ó má tẹ̀ ló tẹ̀ gbẹ̀yìn.
Alénibáre l’ọmọ aráyé.
Wọn a dìtẹ̀,
Wọn a di dúkùú;
Wọn a di tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun danindanin.
Bí wọ́n bá ti kẹ́ẹ́fí ire nínú àyànmọ́.
Wọn a sì fẹ́ rẹ́bùrú àkúnlẹ̀yàn.
Alénibáre ń bẹ nínú ẹbí.
Alénibáre ń bẹ nínú ìjọ.
Alénibáre ń bẹ nínú ẹgbẹ́.
Alénibáre ń bẹ láàárín ọ̀gbà.
Àránnú ni wọ́n á fẹ́ fi bá’hun tó dùn jẹ́.
K’Ádániwáyé ó tó mú kádàrá ẹni ṣẹ.
Wọn a sáré sáré,
Wọn a pọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni wọn ‘ò kúkú gbèrò ire.
Ọ̀pọ̀ alébáre sì ní ń gbèrò ìkà.
A dúpẹ́ pé k’ábanijẹ́ ó tó jí;
Ṣe ló báni lọ́wọ́ atúnnișe.
Ẹni eégún ń lé máa rọ́jú.
Ń’torí bó ti ń rẹ ará ayé,
Ló kúkú ń rẹ ará ọ̀run kìnǹkin.
Ọmọ aráyé lé wa, a sáré kúșẹ́kúșẹ́.
Àșé ṣe ni wọ́n lé wa báre ni.
Ǹjẹ́ ẹni aráyé ń hánnà lọ́wọ́lọ́wọ́;
Bí wọ́n bá lé ọ,
Ìwọ náà má wararo.
Oríire n’ọ́n ń lé ọ lọ bá,
Ìwọ șáà ni ‘ò mọ̀.

Abéjidé Ìgè Àdùbí,
Ibi Orí mi ó bàá ti sunhàn jù báyìí,
Olódùmarè dákun dábọ̀,
Gbé mi dé’bẹ̀ láìwararo.
Fi mí jẹrí àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn.

🙏🙏🙏🙏🙏🙏🙏🙏🙏🙏🙏🙏🙏🙏🙏

Àmín àṣẹ ooooooo.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here